Aworan ami idanimọ ọlọpaa ati afihan aja

ORÍṢUN ÀWÒRÁN,GETTY IMAGES

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara lawọnti bẹrẹ iṣẹlẹ kayeefi kan nibi ti aja ti le arakunrin kan nilu Ilorin sẹnu iku.

Orukọ arakunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn to kagbako iku gbona yi a si maa jẹ Mohammed Faworaja.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ, onimọ ẹrọ ni Mohammed ṣe ti o sin n gbe ni adugbo Wara Osin niluu Ilorin.

Ẹja alagolo taa mọ si Sardine ni Mohammed lọ ra ki o to pade aja to le titi to fi ko sẹnu iku

Ara adugbo kan nibi ti iṣẹlẹ yi ti waye to si ni ka fi orukọ bo ohun laṣiri sọ pe agolo Sandiiini ni Faworaja lọ ra to si n pada si ile rẹ.

O ni ṣadede ni aja kan yọ si Muhammed to si bẹrẹ si nii le.

O le titi debi pe Mohammed faya gba opo ina ti eleyi si ṣokunfa ki ẹjẹ maa jade lẹnu rẹ.

"Aja kan to jẹ ẹya ti wọn pe ni German Sheperd lo sọnu, to si n le oloogbe yii lọ titi to fi lọọ faya gba opo ina ti ẹjẹ si n jade lara rẹ.Lẹsẹkẹsẹ lo ku.Ẹja sandiini to lọọ ra gan-an wa lẹgbẹ opo ina to ku si."

Iku Mohammed ti sọ awọn mọlẹbi rẹ sinu ibanujẹ gẹgẹ baa ṣe gbọ.

Aworan ami afihan ileeṣẹ ọlọpaa

ORÍṢUN ÀWÒRÁN,AFP

Aladugbo yii je ko di mimo pe, eeyan jẹjẹ, oniwa irẹlẹ ni ọdọmọkunrin to ku yii.

O fikun pe olu ọmọ lo jẹ ninu mọlẹbi wọn.

O ṣalaye pe baba rẹ ti fẹyinti lẹnu isẹ to si ti ko gbogbo nnkan le e lọwọ ki ọlọjọ to de.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ni Kwara, SP Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

O ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ati pe geeti ile kan lagbegbe naa ni wọn ṣi silẹ ti aja wọn si jade sita to bẹrẹ si ni le oloogbe yii.

Ẹwẹ, ileesẹ ọlọpaa ti mu ẹni to ni aja naa ti iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.